Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 16:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Awa ti gbọ́ ti igberaga Moabu; o gberaga pọju: ani ti irera rẹ̀, ati igberaga rẹ̀, ati ibinu rẹ̀; ihalẹ rẹ̀ asan ni.

7. Nitorina ni Moabu yio hu fun Moabu, gbogbo wọn o hu: nitori ipilẹ Kir-haresi li ẹnyin o gbàwẹ; nitõtọ a lù wọn.

8. Nitori igbẹ́ Heṣboni rọ, ati àjara Sibma: awọn oluwa awọn keferi ti ke pataki ọ̀gbin rẹ̀ lu ilẹ, nwọn tàn de Jaseri, nwọn nrìn kakiri aginjù: ẹka rẹ̀ nà jade, nwọn kọja okun.

9. Nitorina emi o pohùnrére ẹkun, bi ẹkun Jaseri, àjara Sibma: emi o fi omije mi rin ọ, iwọ Heṣboni, ati Eleale: nitori ariwo nla ta lori èso-igi ẹ̃rùn rẹ, ati lori ikore rẹ.

10. A si mu inu-didun kuro, ati ayọ̀ kuro ninu oko ti nso eso ọ̀pọlọpọ; orin kì yio si si mọ ninu ọgbà-àjara, bẹ̃ni kì yio si ihó-ayọ̀ mọ: afọnti kì yio fọn ọti-waini mọ ninu ifọnti wọn, emi ti mu ariwo dá.

11. Nitorina inu mi yio dún bi harpu fun Moabu, ati ọkàn mi fun Kir-haresi.

12. Yio si ṣe, nigbati a ba ri pe ãrẹ̀ mú Moabu ni ibi giga, ni yio wá si ibi-mimọ́ rẹ̀ lati gbadura; ṣugbọn kì yio bori.

13. Eyi li ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti Moabu lati igbà na wá.

14. Ṣugbọn nisisiyi Oluwa ti sọ̀rọ, wipe, Niwọn ọdun mẹta, gẹgẹ bi ọdun alagbaṣe, a o si kẹgàn ogo Moabu, pẹlu gbogbo ọ̀pọlọpọ nì: awọn iyokù yio kere, kì yio si li agbara.

Ka pipe ipin Isa 16