Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 14:20-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. A kì o sin ọ pọ̀ pẹlu wọn, nitoriti iwọ ti pa ilẹ rẹ run, o si ti pa awọn enia rẹ: iru awọn oluṣe buburu li a kì o darukọ lailai.

21. Mura ibi pipa fun awọn ọmọ rẹ̀, nitori aiṣedẽde awọn baba wọn; ki nwọn ki o má ba dide, ki nwọn ni ilẹ na, ki nwọn má si fi ilu-nla kun oju aiye.

22. Nitori emi o dide si wọn, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ke orukọ ati iyokù kuro ni Babiloni, ati ọmọ, ati ọmọ de ọmọ, ni Oluwa wi.

23. Emi o si ṣe e ni ilẹ-ini fun õrẹ̀, ati àbata omi; emi o si fi ọwọ̀ iparun gbá a, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

24. Oluwa awọn ọmọ-ogun ti bura, wipe, Lõtọ gẹgẹ bi mo ti gberò, bẹ̃ni yio ri, ati gẹgẹ bi mo ti pinnu, bẹ̃ni yio si duro:

25. Pe, emi o fọ́ awọn ara Assiria ni ilẹ mi, ati lori oke mi li emi o tẹ̀ ẹ mọlẹ labẹ ẹsẹ: nigbana li ajàga rẹ̀ yio kuro lara wọn, ati ẹrù rẹ̀ kuro li ejiká wọn.

26. Eyi ni ipinnu ti a pinnu lori gbogbo aiye: eyi si ni ọwọ́ ti a nà jade lori gbogbo orilẹ-ède.

27. Nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pinnu, tani yio si sọ ọ di asan? ọwọ́ rẹ̀ si nà jade, tani yio si dá a padà?

28. Li ọdun ti Ahasi ọba kú, li ọ̀rọ-imọ yi wà.

29. Iwọ máṣe yọ̀, gbogbo Filistia, nitori paṣan ẹniti o nà ọ ṣẹ́; nitori lati inu gbòngbo ejo ni pãmọlẹ kan yio jade wá, irú rẹ̀ yio si jẹ́ ejò iná ti nfò.

30. Akọbi awọn otòṣi yio si jẹ, awọn alaini yio si dubulẹ lailewu; emi o si fi iyàn pa gbòngbo rẹ, on o si pa iyokù rẹ.

31. Hu, iwọ ẹnu-odi; kigbe, iwọ ilu; gbogbo Palestina, iwọ ti di yiyọ́: nitori ẹ̃fin yio ti ariwa jade wá, ẹnikan kì yio si yà ara rẹ̀ kuro lọdọ ẹgbẹ́ rẹ̀.

32. Èsi wo li a o fi fun awọn ikọ̀ orilẹ-ède? Pe, Oluwa ti tẹ̀ Sioni dó, talaka ninu awọn enia rẹ̀ yio si sá wọ̀ inu rẹ̀.

Ka pipe ipin Isa 14