Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 14:16-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Awọn ti o ri ọ yio tẹjumọ ọ, nwọn o si ronu rẹ pe, Eyi li ọkunrin na ti o mu aiye wárìrì, ti o mu ilẹ ọba mìtiti;

17. Ti o sọ aiye dàbi agìnju, ti o si pa ilu rẹ̀ run; ti kò dá awọn ondè rẹ̀ silẹ lati lọ ile?

18. Gbogbo ọba awọn orilẹ-ède, ani gbogbo wọn, dubulẹ ninu ogo, olukuluku ninu ile rẹ̀.

19. Ṣugbọn iwọ li a gbe sọnù kuro nibi iboji rẹ bi ẹka irira, bi aṣọ awọn ti a pa, awọn ti a fi idà gun li agunyọ, ti nsọkalẹ lọ si ihò okuta; bi okú ti a tẹ̀ mọlẹ.

20. A kì o sin ọ pọ̀ pẹlu wọn, nitoriti iwọ ti pa ilẹ rẹ run, o si ti pa awọn enia rẹ: iru awọn oluṣe buburu li a kì o darukọ lailai.

21. Mura ibi pipa fun awọn ọmọ rẹ̀, nitori aiṣedẽde awọn baba wọn; ki nwọn ki o má ba dide, ki nwọn ni ilẹ na, ki nwọn má si fi ilu-nla kun oju aiye.

22. Nitori emi o dide si wọn, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ke orukọ ati iyokù kuro ni Babiloni, ati ọmọ, ati ọmọ de ọmọ, ni Oluwa wi.

23. Emi o si ṣe e ni ilẹ-ini fun õrẹ̀, ati àbata omi; emi o si fi ọwọ̀ iparun gbá a, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

24. Oluwa awọn ọmọ-ogun ti bura, wipe, Lõtọ gẹgẹ bi mo ti gberò, bẹ̃ni yio ri, ati gẹgẹ bi mo ti pinnu, bẹ̃ni yio si duro:

25. Pe, emi o fọ́ awọn ara Assiria ni ilẹ mi, ati lori oke mi li emi o tẹ̀ ẹ mọlẹ labẹ ẹsẹ: nigbana li ajàga rẹ̀ yio kuro lara wọn, ati ẹrù rẹ̀ kuro li ejiká wọn.

26. Eyi ni ipinnu ti a pinnu lori gbogbo aiye: eyi si ni ọwọ́ ti a nà jade lori gbogbo orilẹ-ède.

27. Nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pinnu, tani yio si sọ ọ di asan? ọwọ́ rẹ̀ si nà jade, tani yio si dá a padà?

28. Li ọdun ti Ahasi ọba kú, li ọ̀rọ-imọ yi wà.

Ka pipe ipin Isa 14