Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 11:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẼKÀN kan yio si jade lati inu kùkute Jesse wá, ẹka kan yio si hù jade lati inu gbòngbo rẹ̀:

2. Ẹmi Oluwa yio si bà le e, ẹmi ọgbọ́n ati oye, ẹmi igbimọ̀ ati agbara, ẹmi imọ̀ran ati ibẹ̀ru Oluwa.

3. Õrùn-didùn rẹ̀ si wà ni ibẹ̀ru Oluwa, on ki yio si dajọ nipa ìri oju rẹ̀, bẹ̃ni ki yio dajọ nipa gbigbọ́ eti rẹ̀;

4. Ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tutù aiye; on o si fi ọgọ ẹnu rẹ̀ lu aiye, on o si fi ẽmi ète rẹ̀ lu awọn enia buburu pa.

5. Ododo yio si jẹ amure ẹgbẹ́ rẹ̀, ati iṣotitọ amure inu rẹ̀.

6. Ikõkò pẹlu yio ma ba ọdọ-agutan gbe pọ̀, kiniun yio si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ malũ ati ọmọ kiniun ati ẹgbọ̀rọ ẹran abọpa yio ma gbe pọ̀; ọmọ kekere yio si ma dà wọn.

7. Malũ ati beari yio si ma jẹ pọ̀; ọmọ wọn yio dubulẹ pọ̀; kiniun yio si jẹ koriko bi malũ.

8. Ọmọ ẹnu-ọmu yio si ṣire ni ihò pãmọlẹ, ati ọmọ ti a já lẹnu-ọmu yio si fi ọwọ́ rẹ̀ si ihò ejò.

9. Nwọn ki yio panilara, bẹ̃ni nwọn ki yio panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi: nitori aiye yio kún fun ìmọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bò okun.

10. Ati li ọjọ na kùkute Jesse kan yio wà, ti yio duro fun ọpágun awọn enia; on li awọn keferi yio wá ri: isimi rẹ̀ yio si li ogo.

Ka pipe ipin Isa 11