Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 1:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ilẹ nyin di ahoro, a fi iná kun ilu nyin: ilẹ nyin, alejo jẹ ẹ run li oju nyin, o si di ahoro, bi eyiti awọn alejo wó palẹ.

8. Ọmọbinrin Sioni li a si fi silẹ bi agọ ninu ọgbà àjara, bi abule ninu ọgbà ẹ̀gúsí, bi ilu ti a dóti.

9. Bikòṣe bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi iyokù diẹ kiun silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, awa iba si ti dabi Gomorra.

10. Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin olori Sodomu; fi eti si ofin Ọlọrun wa, ẹnyin enia Gomorra.

11. Oluwa ni, kini ọ̀pọlọpọ ẹbọ nyin jasi fun mi? emi kún fun ọrẹ sisun agbò, ati fun ọrá ẹran abọ́pa; bẹ̃ni emi kò si ni inu didùn si ẹjẹ akọ malũ, tabi si ti ọdọ-agutan, tabi si ti obúkọ.

12. Nigbati ẹnyin wá lati fi ara hàn niwaju mi, tali o bere eyi lọwọ nyin, lati tẹ̀ agbalá mi?

13. Ẹ má mu ọrẹ asan wá mọ́: turari jasi ohun irira fun mi; oṣù titun ati ọjọ isimi, ìpe ajọ, emi kò le rọju gbà; ẹ̀ṣẹ ni, ani apèjọ ọ̀wọ nì.

14. Oṣù titun nyin ati ajọ ìdasilẹ nyin, ọkàn mi korira; nwọn jasi iyọlẹnu fun mi; o sú mi lati gbà wọn.

15. Nigbati ẹnyin si nà ọwọ́ nyin jade, emi o pa oju mi mọ fun nyin: nitõtọ, nigbati ẹnyin ba gbà adura pupọ, emi kì yio gbọ́: ọwọ́ nyin kún fun ẹ̀jẹ.

16. Ẹ wẹ̀, ki ẹ mọ́; mu buburu iṣe nyin kuro niwaju oju mi: dawọ duro lati ṣe buburu;

17. Kọ́ lati ṣe rere; wá idajọ, ràn awọn ẹniti a nilara lọwọ, ṣe idajọ alainibaba, gbà ẹjọ opó rò.

18. Oluwa wipe, wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ̀: bi ẹ̀ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didì; bi nwọn pọ́n bi àlãri, nwọn o dabi irun-agutan.

Ka pipe ipin Isa 1