Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 1:23-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Awọn ọmọ-alade rẹ di ọlọ̀tẹ, ati ẹgbẹ olè: olukuluku nfẹ́ ọrẹ, o si ntọ̀ erè lẹhin: nwọn kò ṣe idajọ alainibaba, bẹ̃ni ọ̀ran opó kò wá sọdọ wọn.

24. Nitorina Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ẹni alagbara Israeli, wipe, A, emi o fi aiya balẹ niti awọn ọtá mi, emi o si gbẹ̀san lara awọn ọtá mi.

25. Emi o yi ọwọ́ mi si ara rẹ, emi o si yọ́ ìdarọ́ rẹ kuro patapata, emi o si mu gbogbo tanganran rẹ kuro:

26. Emi o si mu awọn onidajọ rẹ pada bi igbà iṣãju, ati awọn igbìmọ rẹ bi igbà akọbẹ̀rẹ: lẹhin na, a o pè ọ ni, Ilu ododo, ilu otitọ.

27. Idajọ li a o fi rà Sioni pada, ati awọn ti o pada bọ̀ nipa ododo.

28. Iparun awọn alarekọja pẹlu awọn ẹlẹṣẹ yio wà pọ̀, ati awọn ti o kọ̀ Oluwa silẹ li a o parun.

29. Nitoriti oju yio tì wọn niti igi-nla ti ẹnyin ti fẹ, a o si dãmu nyin niti ọgbà ti ẹnyin ti yàn.

30. Nitori ẹnyin o dabi igi-nla ti ewe rẹ̀ rọ, ati bi ọgbà ti kò ni omi.

31. Alagbara yio si dabi ògùṣọ̀, iṣẹ rẹ̀ yio si dabi ẹta-iná, ati awọn mejeji yio jọ jona pọ̀, ẹnikẹni kì yio si pa wọn.

Ka pipe ipin Isa 1