Gbogbo awọn ọmọ Israeli si ri bi iná na ti bọ́ silẹ, ati ogo Oluwa sori ile na, nwọn doju wọn bò ilẹ ti a fi okuta tẹ́, nwọn si tẹriba, nwọn si yìn Oluwa, wipe, Nitoriti o ṣeun; nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.