Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 4:17-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ni pẹtẹlẹ Jordani ni ọba dà wọn, ni ilẹ amọ̀ li agbedemeji Sukkoti ati Seredata.

18. Bayi ni Solomoni ṣe gbogbo ohun-elo wọnyi li ọ̀pọlọpọ: nitori ti a kò le mọ̀ ìwọn idẹ na.

19. Solomoni si ṣe gbogbo ohun-elo ti iṣe ti ile Ọlọrun, pẹpẹ wura pẹlu, ati awọn tabili lori eyi ti akara ifihan wà;

20. Ọpa-fitila pẹlu ati fitila wọn, ki nwọn ki o ma jo gẹgẹ bi aṣẹ niwaju ibi-mimọ́-jùlọ, jẹ wura daradara.

21. Ati itanna, ati fitila ati ẹ̀mu li o fi wura ṣe; gbogbo eyi ni wura daradara;

22. Ati alumagaji fitila, ati awo-koto, ati ṣibi ati awo-koto turari, wura daradara ni: ati ọ̀na iwọle, awẹ ilẹkun rẹ̀ ti inu lọhun fun ibi-mimọ́-jùlọ, ati awọn ilẹkun fun ile na, ani tempili, wura ni.

Ka pipe ipin 2. Kro 4