Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 33:19-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Adura rẹ̀ na pẹlu, bi Ọlọrun ti gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ati irekọja rẹ̀ ati ibi ti o gbe kọ́ ibi giga wọnni ti o si gbé ere-oriṣa kalẹ, ati awọn ere yiyá, ki a to rẹ̀ ẹ silẹ, kiye si i, a kọ wọn sinu iwe itan Hosai.

20. Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i si ile on tikalarẹ̀: Amoni, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

21. Ẹni ọdun mejidilogun ni Amoni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun meji ni Jerusalemu.

22. O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa, bi Manasse, baba rẹ̀ ti ṣe, nitori Amoni rubọ si gbogbo awọn ere yiyá, ti Manasse baba rẹ̀ ti ṣe, o si sìn wọn:

23. Kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju Oluwa bi Manasse, baba rẹ̀, ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; ṣugbọn Amoni dẹṣẹ pupọpupọ.

24. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si di rikiṣi si i, nwọn si pa a ni ile rẹ̀.

25. Awọn enia ilẹ na si pa gbogbo awọn ti o ti di rikiṣi si Amoni, ọba; awọn enia ilẹ na si fi Josiah, ọmọ rẹ̀, jọba ni ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kro 33