Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 25:21-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Bẹ̃ni Joaṣi, ọba Israeli gòke lọ; nwọn si wò ara wọn li oju, on ati Amasiah, ọba Juda, ni Bet-Ṣemeṣi ti iṣe ti Juda,

22. A si ṣẹ́ Juda niwaju Israeli, nwọn salọ olukuluku sinu agọ rẹ̀.

23. Joaṣi ọba Israeli si mu Amasiah, ọba Juda ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasiah ni Bet-Ṣemeṣi, o si mu u wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu lati ẹnubode Efraimu titi de ẹnu-bode igun, irinwo igbọnwọ.

24. O si mu gbogbo wura ati fadakà, ati gbogbo ohun-elo ti a ri ni ile Ọlọrun lọdọ Obed-Edomu, ati awọn iṣura ile ọba, ati awọn ògo pẹlu, o si pada lọ si Samaria.

25. Amasiah, ọmọ Joaṣi, ọba Juda, wà li ãye lẹhin ikú Joaṣi, ọmọ Jehoahasi ọba Israeli, li ọdun mẹdogun.

26. Ati iyokù iṣe Amasiah, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kò ha kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli?

27. Njẹ lẹhin àkoko ti Amasiah yipada kuro lati ma tọ̀ Oluwa lẹhin, nwọn di ọ̀tẹ si i ni Jerusalemu; o si salọ si Lakiṣi: ṣugbọn nwọn ranṣẹ tẹlẽ ni Lakiṣi, nwọn si pa a nibẹ.

28. Nwọn si mu u wá lori ẹṣin, nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi.

Ka pipe ipin 2. Kro 25