Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 25:20-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́; nitori lati ọdọ Ọlọrun wá ni, ki o le fi wọn le awọn ọta wọn lọwọ, nitoriti nwọn nwá awọn oriṣa Edomu.

21. Bẹ̃ni Joaṣi, ọba Israeli gòke lọ; nwọn si wò ara wọn li oju, on ati Amasiah, ọba Juda, ni Bet-Ṣemeṣi ti iṣe ti Juda,

22. A si ṣẹ́ Juda niwaju Israeli, nwọn salọ olukuluku sinu agọ rẹ̀.

23. Joaṣi ọba Israeli si mu Amasiah, ọba Juda ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasiah ni Bet-Ṣemeṣi, o si mu u wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu lati ẹnubode Efraimu titi de ẹnu-bode igun, irinwo igbọnwọ.

24. O si mu gbogbo wura ati fadakà, ati gbogbo ohun-elo ti a ri ni ile Ọlọrun lọdọ Obed-Edomu, ati awọn iṣura ile ọba, ati awọn ògo pẹlu, o si pada lọ si Samaria.

25. Amasiah, ọmọ Joaṣi, ọba Juda, wà li ãye lẹhin ikú Joaṣi, ọmọ Jehoahasi ọba Israeli, li ọdun mẹdogun.

26. Ati iyokù iṣe Amasiah, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kò ha kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli?

Ka pipe ipin 2. Kro 25