Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 25:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNI ọdun mẹdọgbọn ni Amasiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkandilọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jehoaddani ti Jerusalemu.

2. O si ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe pẹlu ọkàn pipé.

3. O si ṣe, nigbati a fi idi ijọba na mulẹ fun u, o pa awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o pa ọba, baba rẹ̀,

4. Ṣugbọn kò pa awọn ọmọ wọn, ṣugbọn o ṣe gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin ninu iwe Mose, ti Oluwa ti paṣẹ wipe, Awọn baba kì yio kú fun awọn ọmọ, bẹ̃li awọn ọmọ kì yio kú fun awọn baba, ṣugbọn olukuluku ni yio kú nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

5. Amasiah si kó Juda jọ, o si tò wọn lẹsẹsẹ gẹgẹ bi ile baba wọn, awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati balogun ọrọrun, ani gbogbo Juda ati Benjamini, o si ka iye wọn lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̀ lọ, o si ri wọn li ọkẹ mẹdogun enia ti a yàn, ti o le jade lọ si ogun, ti o si le lo ọ̀kọ ati asà.

Ka pipe ipin 2. Kro 25