Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 21:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. O si rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, gẹgẹ bi ile Ahabu ti ṣe: nitoriti o ni ọmọbinrin Ahabu li aya: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa.

7. Ṣugbọn Oluwa kò fẹ ipa ile Dafidi run, nitori majẹmu ti o ti ba Dafidi da, ati bi o ti ṣe ileri lati fun u ni imọlẹ kan ati fun awọn ọmọ rẹ̀ lailai.

8. Li ọjọ rẹ̀ li awọn ara Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda, nwọn si jẹ ọba fun ara wọn.

9. Nigbana ni Jehoramu rekọja lọ pẹlu awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o ká a mọ, ati awọn olori kẹkẹ́.

10. Sibẹ awọn ara Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda, titi di oni yi. Akokò na pẹlu ni Libna ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ rẹ̀; nitoriti o ti kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ.

11. Pẹlupẹlu o ṣe ibi giga wọnni lori òke Judah, o si mu ki awọn olugbe Jerusalemu ki o ṣe àgbere, o si mu Juda ṣẹ̀.

12. Iwe kan si ti ọdọ Elijah, woli, wá si ọdọ rẹ̀ wipe: Bayi li Oluwa, Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi, nitoriti iwọ kò rìn li ọ̀na Jehoṣafati, baba rẹ, tabi li ọ̀na Asa, ọba Juda;

13. Ṣugbọn ti iwọ rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, iwọ si ti mu Juda ati awọn olugbe Jerusalemu tọ ọ̀na panṣaga, gẹgẹ bi panṣaga ile Ahabu, ati ti iwọ si pa awọn arakunrin ile baba rẹ ti o jẹ ẹni-rere jù iwọ lọ:

14. Kiyesi i, Oluwa yio fi àjakalẹ-arun nla kọlù awọn enia rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn obinrin rẹ, ati gbogbo ọrọ̀ rẹ:

15. Iwọ o ṣe aisan pupọ, àrun nla ninu ifun rẹ, titi ifun rẹ yio fi tu jade nitori àrun ọjọ pupọ.

Ka pipe ipin 2. Kro 21