Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 21:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ṣugbọn ti iwọ rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, iwọ si ti mu Juda ati awọn olugbe Jerusalemu tọ ọ̀na panṣaga, gẹgẹ bi panṣaga ile Ahabu, ati ti iwọ si pa awọn arakunrin ile baba rẹ ti o jẹ ẹni-rere jù iwọ lọ:

14. Kiyesi i, Oluwa yio fi àjakalẹ-arun nla kọlù awọn enia rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn obinrin rẹ, ati gbogbo ọrọ̀ rẹ:

15. Iwọ o ṣe aisan pupọ, àrun nla ninu ifun rẹ, titi ifun rẹ yio fi tu jade nitori àrun ọjọ pupọ.

16. Pẹlupẹlu, Oluwa ru ẹmi awọn ara Filistia, ati ti awọn ara Arabia, ti o sunmọ awọn ara Etiopia, soke si Jehoramu.

17. Nwọn si gòke wá si Juda, nwọn si ya wọle, nwọn si kó gbogbo ọrọ̀ ti a ri ni ile ọba ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, ati awọn obinrin rẹ̀, ni igbekun lọ; tobẹ̃ ti a kò ṣẹ́ku ọkunrin kan silẹ fun u, bikòṣe Jehoahasi, abikẹhin ninu awọn ọmọ rẹ̀.

18. Lẹhin gbogbo eyi Oluwa fi àrun, ti a kò le wòsan, kọlù u ni ifun.

19. O si ṣe bẹ̃ bi akokò ti nlọ ati lẹhin ọdun meji, ni ifun rẹ̀ tu jade nitori aìsan rẹ̀, o si kú ninu irora buburu na: awọn enia rẹ̀ kò si ṣe ijona fun u gẹgẹ bi ijona ti awọn baba rẹ̀.

20. Ẹni ọdun mejilelọgbọn ni nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹjọ ni Jerusalemu, o si fi ilẹ silẹ laiwu ni: nwọn si sìn i ni ilu Dafidi; ṣugbọn kì iṣe ninu iboji awọn ọba.

Ka pipe ipin 2. Kro 21