Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 21:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JEHOṢAFATI si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Jehoramu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2. O si ni awọn arakunrin, awọn ọmọ Jehoṣafati, Asariah, ati Jehieli, ati Sekariah, ati Asariah ati Mikaeli, ati Ṣefatiah: gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Jehoṣafati, ọba Juda.

3. Baba wọn si bun wọn li ẹ̀bun pupọ, ni fadakà ati ni wura, ati ohun iyebiye, pẹlu ilu olodi ni Juda, ṣugbọn o fi ijọba fun Jehoramu: nitori on li akọbi.

4. Nigbati Jehoramu si dide si ijọba baba rẹ̀, o mu ara rẹ̀ le, o si fi idà pa gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati ninu awọn ijoye Israeli.

5. Jehoramu jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọ̀n nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mẹjọ ni Jerusalemu.

6. O si rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, gẹgẹ bi ile Ahabu ti ṣe: nitoriti o ni ọmọbinrin Ahabu li aya: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa.

7. Ṣugbọn Oluwa kò fẹ ipa ile Dafidi run, nitori majẹmu ti o ti ba Dafidi da, ati bi o ti ṣe ileri lati fun u ni imọlẹ kan ati fun awọn ọmọ rẹ̀ lailai.

Ka pipe ipin 2. Kro 21