Awọn ọmọ Ammoni ati Moabu si dide si awọn ti ngbe òke Seiri, lati pa, ati lati run wọn tũtu: nigbati nwọn si pa awọn ti ngbe òke Seiri run tan, ẹnikini nṣe iranlọwọ lati run ẹnikeji.