Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 19:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JEHOṢAFATI, ọba Juda, si pada lọ si ile rẹ̀ ni Jerusalemu li alafia.

2. Jehu, ọmọ Hanani, ariran, si jade lọ ipade rẹ̀, o si wi fun Jehoṣafati pe, iwọ o ha ma ràn enia buburu lọwọ, iwọ o si fẹran awọn ti o korira Oluwa? njẹ nitori eyi ni ibinu ṣe de si ọ lati ọdọ Oluwa.

3. Ṣugbọn a ri ohun rere ninu rẹ, pe, nitori ti iwọ ti mu awọn ere-oriṣa kuro ni ilẹ na, ti o si mura ọkàn rẹ lati wá Ọlọrun.

4. Jehoṣafati si ngbe Jerusalemu: o nlọ, o mbọ̀ lãrin awọn enia lati Beerṣeba de òke Efraimu, o si mu wọn pada sọdọ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn.

5. O si fi awọn onidajọ si ilẹ na, ninu gbogbo ilu olodi Juda, lati ilu de ilu,

Ka pipe ipin 2. Kro 19