Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 18:9-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ati ọba Israeli, ati Jehoṣafati, ọba Juda joko, olukuluku lori itẹ rẹ̀, nwọn si wọ aṣọ igunwa wọn, nwọn si joko ni ita ẹnubọde Samaria; gbogbo awọn woli si nsọ asọtẹlẹ niwaju wọn.

10. Sedekiah ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn awọn ara Siria titi iwọ o fi run wọn.

11. Gbogbo awọn woli si nsọtẹlẹ bẹ̃ wipe, Gòke lọ si Ramoti-Gileadi, iwọ o ṣe rere; Oluwa yio si fi i le ọba lọwọ.

12. Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah si wi fun u pe, Kiye si i, awọn woli fi ẹnu kan sọ rere fun ọba: Njẹ emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọkan ninu ti wọn, ki o si sọ rere.

13. Mikaiah si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ani, eyiti Ọlọrun mi ba wi li emi o sọ.

14. Nigbati o si tọ̀ ọba wá, ọba sọ fun u pe, Mikaiah, ki awa ki o lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? O si wipe, Ẹ lọ, ẹnyin o si ṣe rere, a o si fi wọn le nyin lọwọ.

15. Ọba si wi fun u pe, Igba melo li emi o fi ọ bú ki iwọ ki o máṣe sọ ohun kan fun mi bikòṣe ọ̀rọ otitọ li orukọ Oluwa?

16. On si wipe, Emi ri gbogbo Israeli fọnka kiri lori awọn òke, bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa: jẹ ki nwọn ki o pada, olukuluku si ile rẹ̀ li alafia.

17. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi kò ti wi fun ọ pe: on kì isọtẹlẹ rere si mi, bikòṣe ibi?

18. Mikaiah si wipe, Nitorina, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun ọrun duro lapa ọtún ati lapa òsi rẹ̀.

19. Oluwa si wipe, Tani yio tàn Ahabu, ọba Israeli, ki o le gòke lọ ki o si le ṣubu ni Ramoti-Gileadi? Ekini si sọ bayi, ekeji si sọ miran.

20. Nigbana ni ẹmi na jade wá, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Emi o tàn a. Oluwa si wi fun u pe, Bawo?

21. On si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. Oluwa si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃ na.

22. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, Oluwa ti fi ẹmi eke si ẹnu gbogbo awọn woli rẹ wọnyi, Oluwa si ti sọ ibi si ọ.

23. Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana, sunmọ ọ, o si lù Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà kọja lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ.

24. Mikaiah si wipe, Kiyesi i, iwọ o ri i li ọjọ na, nigbati iwọ o wọ inu iyẹwu de inu iyẹwu lọ ifi ara rẹ pamọ́,

Ka pipe ipin 2. Kro 18