Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 18:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JEHOṢAFATI si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ, o si ba Ahabu dá ana.

2. Lẹhin ọdun melokan, on sọ̀kalẹ tọ Ahabu lọ si Samaria. Ahabu si pa agutan ati malu fun u li ọ̀pọlọpọ ati fun awọn enia ti o pẹlu rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati ba a gòke lọ si Ramoti-Gileadi.

3. Ahabu ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati ọba Juda pe, Iwọ o ha ba mi lọ si Ramoti-Gileadi bi? On si da a li ohùn wipe, Emi bi iwọ, ati enia mi bi enia rẹ; awa o pẹlu rẹ li ogun na.

4. Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa loni.

5. Nitorina ọba Israeli kó awọn woli jọ, irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki awa ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Gòke lọ; Ọlọrun yio si fi i le ọba lọwọ.

6. Ṣugbọn Jehoṣafati wipe, kò si woli Oluwa nihin pẹlu, ti awa ìba bère lọwọ rẹ̀?

7. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan mbẹ sibẹ lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀: nitoriti kò jẹ sọ asọtẹlẹ rere si mi lai, bikòṣe ibi nigbagbogbo: eyini ni Mikaiah, ọmọ Imla. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba ki o má sọ bẹ̃.

8. Ọba Israeli si pè ìwẹfa kan, o si wipe, Mu ki Mikaiah ọmọ Imla, ki o yara wá.

9. Ati ọba Israeli, ati Jehoṣafati, ọba Juda joko, olukuluku lori itẹ rẹ̀, nwọn si wọ aṣọ igunwa wọn, nwọn si joko ni ita ẹnubọde Samaria; gbogbo awọn woli si nsọ asọtẹlẹ niwaju wọn.

10. Sedekiah ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn awọn ara Siria titi iwọ o fi run wọn.

Ka pipe ipin 2. Kro 18