Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 15:12-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nwọn si tun dá majẹmu lati wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, tinutinu wọn ati tọkàntọkàn wọn.

13. Pe, ẹnikẹni ti kò ba wá Oluwa Ọlọrun Israeli, pipa li a o pa a, lati ẹni-kekere de ẹni-nla, ati ọkunrin ati obinrin.

14. Nwọn si fi ohùn rara bura fun Oluwa, ati pẹlu ariwo, ati pẹlu ipè ati pẹlu fère.

15. Gbogbo Juda si yọ̀ si ibura na: nitoriti nwọn fi tinu-tinu wọn bura, nwọn si fi gbogbo ifẹ inu wọn wá a; nwọn si ri i: Oluwa si fun wọn ni isimi yikakiri.

16. Pẹlupẹlu Maaka, iya Asa, li ọba mu u kuro lati má ṣe ayaba, nitoriti o yá ere fun oriṣa rẹ̀: Asa si ké ere rẹ̀ lulẹ, o si tẹ̀ ẹ mọlẹ, o si sun u nibi odò Kidroni.

17. Ṣugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro ni Israeli: kiki ọkàn Asa wà ni pipé li ọjọ rẹ̀ gbogbo.

18. O si mu ohun mimọ́ wọnni ti baba rẹ̀, ati ohun mimọ́ wọnni ti on tikararẹ̀ wá sinu ile Ọlọrun, fadakà, wura, ati ohun-elo wọnni.

19. Ogun kò si mọ titi di ọdun karundilogoji ọba Asa.

Ka pipe ipin 2. Kro 15