Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 13:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nigbati Juda si bojuwo ẹhin, si kiyesi i, ogun mbẹ niwaju ati lẹhin: nwọn si ke pè Oluwa, awọn alufa si fún ipè.

15. Olukuluku, ọkunrin Juda si hó: o si ṣe, bi awọn ọkunrin Juda si ti hó, ni Ọlọrun kọlu Jeroboamu ati gbogbo Israeli niwaju Abijah ati Juda.

16. Awọn ọmọ Israeli si sa niwaju Juda: Ọlọrun si fi wọn le wọn lọwọ.

17. Abijah ati awọn enia rẹ̀ si pa ninu wọn li ọ̀pọlọpọ: bẹ̃ni ọkẹ mẹdọgbọn ọkunrin ti a yàn ṣubu ni pipa ninu Israeli.

18. Bayi li a rẹ̀ awọn ọmọ Israeli silẹ li akoko na, awọn ọmọ Juda si bori nitori ti nwọn gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn.

19. Abijah si lepa Jeroboamu, o si gbà ilu lọwọ rẹ̀, Beteli pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Jeṣana pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Efraimu pẹlu awọn ilu rẹ̀.

20. Bẹ̃ni Jeroboamu kò si tun li agbara mọ li ọjọ Abijah: Oluwa si lù u, o si kú.

21. Abijah si di alagbara, o si gbe obinrin mẹtala ni iyawo, o si bi ọmọkunrin mejilelogun, ati ọmọbinrin mẹrindilogun.

22. Ati iyokù iṣe Abijah, ati iwà rẹ̀, ati iṣẹ rẹ̀, a kọ wọn sinu iwe-itumọ Iddo, woli.

Ka pipe ipin 2. Kro 13