Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 13:11-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nwọn si nsun ọrẹ-ẹbọ sisun ati turari didùn li orowurọ ati li alalẹ si Oluwa: àkara ifihan pẹlu ni nwọn si ntò lori tabili mimọ́; ati ọpa fitila wura pẹlu fitila wọn, lati ma jó lalalẹ; nitori ti awa npa aṣẹ Oluwa Ọlọrun wa mọ́; ṣugbọn ẹnyin kọ̀ ọ silẹ.

12. Si kiyesi i, Ọlọrun tikararẹ̀ si wà pẹlu wa li Olori wa, ati awọn alufa rẹ̀ pẹlu ipè didún ijaiya lati dún si nyin, Ẹnyin ọmọ Israeli, ẹ máṣe ba Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin jà; nitori ẹ kì yio ṣe rere.

13. Ṣugbọn Jeroboamu mu ki ogun-ẹ̀hin ki o bù wọn li ẹhin: bẹ̃ni nwọn mbẹ niwaju Juda, ati ogun-ẹhin na si mbẹ lẹhin wọn.

14. Nigbati Juda si bojuwo ẹhin, si kiyesi i, ogun mbẹ niwaju ati lẹhin: nwọn si ke pè Oluwa, awọn alufa si fún ipè.

15. Olukuluku, ọkunrin Juda si hó: o si ṣe, bi awọn ọkunrin Juda si ti hó, ni Ọlọrun kọlu Jeroboamu ati gbogbo Israeli niwaju Abijah ati Juda.

16. Awọn ọmọ Israeli si sa niwaju Juda: Ọlọrun si fi wọn le wọn lọwọ.

Ka pipe ipin 2. Kro 13