Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 13:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun kejidilogun Jeroboamu, ọba, ni Abijah bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda.

2. O jọba li ọdun mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Mikaiah ọmọbinrin Urieli ti Gibea, ọtẹ si wà lãrin Abijah ati Jeroboamu.

3. Abijah si fi awọn alagbara akọni ologun dì ogun na, ani ogún ọkẹ́ enia ti a yàn, Jeroboamu pẹlu si fi ogoji ọkẹ enia ti a yàn, awọn alagbara akọni enia tẹ́ ogun si i.

4. Abijah si duro lori oke Semaraimu, ti o wà li òke Efraimu, o si wipe, Ẹ gbọ́ temi, Jeroboamu ati gbogbo Israeli!

5. Kò ha tọ́ ki ẹnyin ki o mọ̀ pe: Oluwa Ọlọrun Israeli fi ijọba lori Israeli fun Dafidi lailai, ani fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa majẹmu iyọ̀?

Ka pipe ipin 2. Kro 13