Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 10:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. REHOBOAMU si lọ si Ṣekemu: nitori gbogbo Israeli wá si Ṣekemu lati fi i jẹ ọba.

2. O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọmọ Nebati gbọ́, on si wà ni Egipti nibiti o ti salọ kuro niwaju Solomoni ọba, ni Jeroboamu pada ti Egipti wá.

3. Nwọn si ranṣẹ pè e. Bẹ̃ni Jeroboamu ati gbogbo Israeli wá, nwọn si ba Rehoboamu sọ̀rọ, wipe,

4. Baba rẹ mu ki àjaga wa ki o wuwo: njẹ nisisiyi iwọ ṣẹkù kuro ninu ìsin baba rẹ ti o nira, ati àjaga wuwo rẹ̀ ti o fi bọ̀ wa lọrùn, awa o si ma sìn ọ.

5. On si wi fun wọn pe, Ẹ tun pada tọ̀ mi wá lẹhin ijọ mẹta. Awọn enia na si lọ.

6. Rehoboamu ọba si ba awọn àgbagba ti o ti nduro niwaju Solomoni baba rẹ̀; nigbati o wà lãye dá imọran, wipe, imọran kili ẹnyin dá lati da awọn enia yi lohùn?

7. Nwọn si ba a sọ̀rọ pe, bi iwọ ba ṣe ire fun enia yi, ti iwọ ba ṣe ohun ti o wù wọn, ti o ba si sọ̀rọ rere fun wọn, nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ nigbagbogbo.

8. Ṣugbọn o kọ̀ imọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti o dàgba pẹlu rẹ̀ damọran, ti o duro niwaju rẹ̀.

9. On si wi fun wọn pe, Imọran kili ẹnyin dá, ki awa ki o le da awọn enia yi lohùn, ti o ba mi sọ̀rọ, wipe, Ṣe ki àjaga ti baba rẹ fi bọ̀ wa lọrùn ki o fuyẹ diẹ?

10. Awọn ipẹrẹ ti a tọ́ pẹlu rẹ̀ si sọ fun u wipe, Bayi ni iwọ o da awọn enia na li ohùn ti o sọ fun ọ, wipe, Baba rẹ mu àjaga wa di wuwo, ṣugbọn iwọ ṣe e ki o fẹrẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o wi fun wọn, Ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ.

11. Njẹ nisisiyi baba mi ti fi àjaga wuwo bọ̀ nyin lọrùn, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin.

12. Jeroboamu ati gbogbo awọn enia si tọ̀ Rehoboamu wá ni ijọ kẹta gẹgẹ bi ọba ti dá, wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta.

13. Nigbana ni ọba da wọn li ohùn akọ; Rehoboamu ọba si kọ̀ imọran awọn àgbagba silẹ.

14. O si da wọn li ohùn gẹgẹ bi imọran awọn ipẹrẹ, wipe, Baba mi mu àjaga nyin ki o wuwo, ṣugbọn emi o fi kún u; baba mi ti fi paṣan nà nyin, ṣugbọn emi o fi akẽke nà nyin.

Ka pipe ipin 2. Kro 10