Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 1:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. A si mu Solomoni, ọmọ Dafidi, lagbara lori ijọba rẹ̀, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ si wà pẹlu rẹ̀, o si gbé e ga gidigidi.

2. Solomoni si sọ fun gbogbo Israeli, fun awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati fun awọn onidajọ, ati fun gbogbo awọn bãlẹ ni gbogbo Israeli, awọn olori awọn baba.

3. Solomoni ati gbogbo awọn ijọ enia pẹlu rẹ̀, lọ si ibi giga ti o wà ni Gibeoni; nitori nibẹ ni agọ ajọ enia Ọlọrun gbe wà, ti Mose, iranṣẹ Oluwa ti pa ni aginju.

4. Apoti-ẹri Ọlọrun ni Dafidi ti gbé lati Kirjat-jearimu wá si ibi ti Dafidi ti pese silẹ fun u, nitoriti o ti pa agọ kan silẹ fun u ni Jerusalemu.

5. Ṣugbọn pẹpẹ idẹ ti Besaleeli, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ṣe, wà nibẹ niwaju agọ Oluwa: Solomoni ati ijọ enia si wá a ri.

6. Solomoni si lọ si ibi pẹpẹ idẹ niwaju Oluwa, ti o ti wà nibi agọ ajọ, o si rú ẹgbẹrun ẹbọ-sisun lori rẹ̀.

7. Li oru na li Oluwa fi ara hàn Solomoni, o si wi fun u pe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ.

8. Solomoni si wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti fi ãnu nla hàn baba mi, o si ti mu mi jọba ni ipò rẹ̀.

9. Nisisiyi Oluwa Ọlọrun, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ fun Dafidi baba mi ṣẹ: nitoriti iwọ ti fi mi jọba lori awọn enia ti o pọ̀ bi erupẹ ilẹ.

Ka pipe ipin 2. Kro 1