Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 8:13-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. On o si mu ninu ọmọbinrin nyin ṣe olùṣe ikunra õrun didùn, ati ẹniti yio ma ṣe alasè, ati ẹniti yio ma ṣe akara.

14. Yio mu ninu oko nyin, ati ninu ọgba ajara nyin, ati ninu igi olifi nyin wọnni, ani eyiti o dara julọ ninu wọn, yio si fi fun awọn ẹrú rẹ̀.

15. On o si mu idamẹwa ninu irugbin nyin, ati ọgbà ajara nyin, yio si fi fun awọn ẹmẹ̀wa rẹ̀ ati fun awọn ẹrú rẹ̀.

16. Yio mu awọn ẹrúkunrin nyin, ati ẹrubirin nyin, ati awọn aṣàyàn ọdọmọkunrin nyin, ati awọn kẹtẹkẹtẹ nyin, yio si fi nwọn si iṣẹ ara rẹ̀.

17. On o si mu idamẹwa ninu awọn agutan nyin: ẹnyin o si jasi ẹrú rẹ̀.

18. Ẹnyin o kigbe fun igbala li ọjọ na nitori ọba nyin ti ẹnyin o yàn: Oluwa kì yio gbọ́ ti nyin li ọjọ na.

19. Ṣugbọn awọn enia na kọ̀ lati gbọ́ ohùn Samueli; nwọn si wipe, bẹ̃kọ; awa o ni ọba lori wa;

20. Ani awa o si dabi gbogbo orilẹ-ède; ki ọba wa ki o si ma ṣe idajọ wa, ki o si ma ṣaju wa, ki o si ma ja ogun wa.

21. Samueli si gbọ́ gbogbo ọ̀rọ awọn enia na, o si sọ wọn li eti Oluwa.

22. Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn wọn ki o si fi ọba jẹ fun wọn. Samueli sọ fun awọn ọmọ Israeli pe. Lọ, olukuluku si ilu rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Sam 8