Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 7:9-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Samueli mu ọdọ-agutan kan ti nmu ọmu, o si fi i ru ọtọtọ ẹbọ sisun si Oluwa: Samueli si ke pe Oluwa fun Israeli; Oluwa si gbọ́ ọ.

10. Bi Samueli ti nru ẹbọ sisun na lọwọ́, awọn Filistini si sunmọ Israeli lati ba wọn jà: ṣugbọn Oluwa sán ãrá nla li ọjọ na sori awọn Filistini, o si damu wọn, o si pa wọn niwaju Israeli.

11. Awọn ọkunrin Israeli si jade kuro ni Mispe, nwọn si le awọn Filistini, nwọn si npa wọn titi nwọn fi de abẹ Betkari.

12. Samueli si mu okuta kan, o si gbe e kalẹ lagbedemeji Mispe ati Seni, o si pe orukọ rẹ̀ ni Ebeneseri, wipe: Titi de ihin li Oluwa ràn wa lọwọ́.

13. Bẹ̃li a tẹ ori awọn Filistini ba, nwọn kò si tun wá si agbegbe Israeli mọ: ọwọ́ Oluwa si wà ni ibi si awọn Filistini, ni gbogbo ọjọ Samueli.

14. Ilu wọnni eyi ti awọn Filistini ti gbà lọwọ Israeli ni nwọn si fi fun Israeli, lati Ekroni wá titi o fi de Gati; ati agbegbe rẹ̀, ni Israeli gbà silẹ lọwọ́ awọn Filistini. Irẹpọ si wà larin Israeli ati awọn Amori.

15. Samueli ṣe idajọ Israeli ni gbogbo ọjọ rẹ̀.

16. Lati ọdun de ọdun li on ima lọ yika Beteli, ati Gilgali, ati Mispe, on si ṣe idajọ Israeli ni gbogbo ibẹ wọnni.

17. On a si ma yipada si Rama: nibẹ ni ile rẹ̀ gbe wà; nibẹ na li on si ṣe idajọ Israeli, o si tẹ pẹpẹ nibẹ fun Oluwa.

Ka pipe ipin 1. Sam 7