Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 7:3-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Samueli si sọ fun gbogbo ile Israeli, wipe, Bi ẹnyin ba fi gbogbo ọkàn nyin yipada si Oluwa, ẹ mu ajeji ọlọrun wọnni, ati Aṣtaroti kuro larin nyin, ki ẹnyin ki o si pese ọkàn nyin silẹ fun Oluwa, ki ẹ si ma sin on nikanṣoṣo: yio si gbà nyin lọwọ́ Filistini.

4. Awọn ọmọ Israeli si mu Baalimu ati Aṣtaroti kuro, nwọn si sìn Oluwa nikan.

5. Samueli si wipe, Pe gbogbo Israeli jọ si Mispe, emi o si bẹbẹ si Oluwa fun nyin,

6. Nwọn si pejọ si Mispe, nwọn pọn omi, nwọn si tú u silẹ niwaju Oluwa, nwọn gbawẹ li ọjọ na, nwọn si wi nibẹ pe, Awa ti dẹṣẹ si Oluwa. Samueli si ṣe idajọ awọn ọmọ Israeli ni Mispe.

7. Awọn Filistini si gbọ́ pe, awọn ọmọ Israeli pejọ si Mispe, awọn ijoye Filistini si goke tọ Israeli lọ. Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, nwọn bẹ̀ru awọn Filistini.

8. Awọn ọmọ Israeli si wi fun Samueli pe, Máṣe dakẹ ati ma ke pe Oluwa Ọlọrun wa fun wa, yio si gbà wa lọwọ́ awọn Filistini.

9. Samueli mu ọdọ-agutan kan ti nmu ọmu, o si fi i ru ọtọtọ ẹbọ sisun si Oluwa: Samueli si ke pe Oluwa fun Israeli; Oluwa si gbọ́ ọ.

Ka pipe ipin 1. Sam 7