Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 5:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN Filistini si gbe Apoti Ọlọrun, nwọn si mu u lati Ebeneseri wá si Aṣdodu.

2. Nigbati awọn Filistini gbe apoti Ọlọrun, nwọn si gbe e wá si ile Dagoni, nwọn gbe e kà ilẹ li ẹba Dagoni.

3. Nigbati awọn ara Aṣdodu ji li owurọ ọjọ keji, kiye si i, Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju apoti Oluwa. Nwọn si gbe Dagoni, nwọn si tun fi i si ipò rẹ̀.

4. Nigbati nwọn ji li owurọ̀ ọjọ keji, kiyesi i, Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju apoti Oluwa; ati ori Dagoni ati atẹlẹ ọwọ́ rẹ̀ mejeji ke kuro li oju ọ̀na; Dagoni ṣa li o kù fun ara rẹ̀.

5. Nitorina awọn alufa Dagoni, ati gbogbo awọn ti ima wá si ile Dagoni, kò si tẹ oju ọ̀na Dagoni ni Aṣdodu titi di oni.

6. Ọwọ́ Oluwa si wuwo si ara Aṣdodu, o si pa wọn run, o si fi iyọdi pọn wọn loju, ani Aṣdodu ati agbegbe rẹ̀.

7. Nigbati awọn enia Aṣdodu ri pe bẹ̃ li o ri, nwọn si wi pe, Apoti Ọlọrun Israeli kì yio ba wa gbe: nitoripe ọwọ́ rẹ̀ wuwo si wa, ati si Dagoni ọlọrun wa.

Ka pipe ipin 1. Sam 5