Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 4:18-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. O sì ṣe, nigbati o darukọ apoti Ọlọrun, o ṣubu ṣehin kuro lori apoti lẹba bode, ọrun rẹ̀ si ṣẹ, o si kú: nitori o di arugbo tan, o si tobi. O si ṣe idajọ Israeli li ogoji ọdun.

19. Aya ọmọ rẹ̀, obinrin Finehasi, loyun, o si sunmọ ọjọ ibi rẹ̀; nigbati o si gbọ́ ihìn pe a ti gbà apoti Ọlọrun, ati pe, baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ kú, o kunlẹ, o si bimọ, nitori obí tẹ̀ ẹ.

20. Lakoko ikú rẹ̀ awọn obinrin ti o duro tì i si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; nitoriti iwọ bi ọmọkunrin kan. Ko dahun, kò si kà a si.

21. On si pe ọmọ na ni Ikabodu, wipe, Kò si ogo fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun, ati nitori ti baba ọkọ rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀.

22. O si wipe, Ogo kò si fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun.

Ka pipe ipin 1. Sam 4