Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 3:13-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitoriti emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ̀, nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun.

14. Nitorina emi ti bura si ile Eli, pe ìwa-buburu ile Eli li a kì yio fi ẹbọ tabi ọrẹ wẹ̀nù lailai.

15. Samueli dubulẹ titi di owurọ, o si ṣi ilẹkun ile OLUWA. Samueli si bẹru lati rò ifihan na fun Eli.

16. Nigbana ni Eli pe Samueli, o si wipe, Samueli, ọmọ mi. On si dahun pe, Emi nĩ.

17. O si wipe, Kili ohun na ti Oluwa sọ fun ọ? emi bẹ ọ máṣe pa a mọ fun mi: ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si ọ, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ ba pa ohun kan mọ fun mi ninu gbogbo ohun ti o sọ fun ọ.

18. Samueli si rò gbogbo ọ̀rọ na fun u, kò si pa ohun kan mọ fun u. O si wipe, Oluwa ni: jẹ ki o ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀.

19. Samueli ndagba, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀, kò si jẹ ki ọkan ninu ọ̀rọ rẹ̀ wọnni bọ́ silẹ.

Ka pipe ipin 1. Sam 3