Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 3:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌMỌ na Samueli nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli. Ọ̀rọ Oluwa si ṣọwọ́n lọjọ wọnni; ifihàn kò pọ̀.

2. O si ṣe li akoko na, Eli si dubulẹ ni ipo tirẹ̀, oju rẹ̀ bẹrẹ̀ si ṣõkun, tobẹ̃ ti ko le riran.

3. Ki itana Ọlọrun to kú ninu tempeli Oluwa, Samueli dubulẹ nibiti apoti Ọlọrun gbe wà,

4. Oluwa pe Samueli: on si dahun pe, Emi nĩ.

5. O si sare tọ Eli, o si wipe, Emi nĩ; nitori ti iwọ pè mi. On wipe, emi kò pè: pada lọ dubulẹ. O si lọ dubulẹ.

6. Oluwa si tun npè, Samueli. Samueli si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi nĩ; nitoriti iwọ pè mi. O si da a lohun, emi kò pè, ọmọ mi; padà lọ dubulẹ.

7. Samueli ko iti mọ̀ Oluwa, bẹ̃ni a ko iti fi ọ̀rọ Oluwa hàn a.

8. Oluwa si tun Samueli pè lẹ̃kẹta. O si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi nĩ; nitori iwọ pè mi. Eli, si mọ̀ pe, Oluwa li o npe ọmọ na.

9. Nitorina Eli wi fun Samueli pe, Lọ dubulẹ: yio si ṣe, bi o ba pè ọ, ki iwọ si wipe, ma wi, Oluwa; nitoriti iranṣẹ rẹ ngbọ́. Bẹ̃ni Samueli lọ, o si dubulẹ nipò tirẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Sam 3