Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 24:15-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ki Oluwa ki o ṣe onidajọ, ki o si dajọ larin emi ati iwọ, ki o si wò ki o gbejà mi, ki o si gbà mi kuro li ọwọ́ rẹ.

16. O si ṣe, nigbati Dafidi si dakẹ ọ̀rọ wọnyi isọ fun Saulu, Saulu si wipe, Ohùn rẹ li eyi bi, Dafidi ọmọ mi? Saulu si gbe ohùn rẹ̀ soke, o sọkun.

17. O si wi fun Dafidi pe, Iwọ ṣe olododo jù mi lọ: nitoripe iwọ ti fi ire san fun mi, emi fi ibi san fun ọ.

18. Iwọ si fi ore ti iwọ ti ṣe fun mi hàn loni: nigbati o jẹ pe, Oluwa ti fi emi le ọ li ọwọ́, iwọ kò si pa mi.

19. Nitoripe bi enia ba ri ọta rẹ̀, o le jẹ ki o lọ li alafia bi? Oluwa yio si fi ire san eyi ti iwọ ṣe fun mi loni.

20. Wõ, emi mọ̀ nisisiyi pe, nitotọ iwọ o jẹ ọba, ilẹ-ọba Israeli yio si fi idi mulẹ si ọ lọwọ.

21. Si bura fun mi nisisiyi li orukọ Oluwa, pe, iwọ kì yio ke iru mi kuro lẹhin mi, ati pe, iwọ ki yio pa orukọ mi run kuro ni idile baba mi.

22. Dafidi si bura fun Saulu. Saulu si lọ si ile rẹ̀; ṣugbọn Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ si iho na.

Ka pipe ipin 1. Sam 24