Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 19:10-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Saulu ti nwá ọ̀na lati fi ẹṣín na gún Dafidi mọ ogiri: ṣugbọn on si yẹra kuro niwaju Saulu: o si sọ ẹṣín na wọnu ogiri: Dafidi si sa, o si fi ara pamọ li oru na.

11. Saulu si rán onṣẹ si ile Dafidi, lati ma ṣọ ọ ati lati pa a li owurọ: Mikali aya Dafidi si wi fun u pe, Bi iwọ kò ba gbà ẹmi rẹ là li alẹ yi, li ọla li a o pa ọ.

12. Mikali si sọ Dafidi kalẹ lati oju ferese kan wá; on si lọ, o sa, o si fi ara rẹ̀ pamọ.

13. Mikali si mu ere, o si tẹ́ ẹ sori akete, o si fi timtim onirun ewurẹ sibẹ fun irọri rẹ̀, o si fi aṣọ bò o.

14. Nigbati Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi, on si wi fun wọn pe, Kò sàn.

15. Saulu si tun ran awọn onṣẹ na lọ iwo Dafidi, o wi pe, Gbe e goke tọ̀ mi wá ti-akete ti-akete ki emi ki o pa a.

16. Nigbati awọn onṣẹ na de, sa wõ, ere li o si wà lori akete, ati timtim onirun ewurẹ fun irọri rẹ̀.

17. Saulu si wi fun Mikali pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi tàn mi jẹ bẹ̃, ti iwọ si fi jọwọ ọta mi lọwọ lọ, ti on si bọ? Mikali si da Saulu lohùn pe, On wi fun mi pe, Jẹ ki emi lọ; ẽṣe ti emi o fi pa ọ?

18. Dafidi si sa, o si bọ, o si tọ Samueli wá ni Rama, o si rò fun u gbogbo eyi ti Saulu ṣe si i. On ati Samueli si lọ, nwọn si ngbe Naoti.

19. A si wi fun Saulu pe, Wõ, Dafidi mbẹ ni Naoti ni Rama.

Ka pipe ipin 1. Sam 19