Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 15:24-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Saulu si wi fun Samueli pe, Emi ti ṣẹ̀: nitoriti emi ti re ofin Oluwa kọja, ati ọ̀rọ rẹ̀: nitori emi bẹ̀ru awọn enia, emi si gbà ohùn wọn gbọ́.

25. Ṣugbọn nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ mi jì mi, ki o sì yipada pẹlu mi, ki emi ki o le tẹriba niwaju Oluwa.

26. Samueli si wi fun Saulu pe, emi kì yio tun yipada pẹlu rẹ mọ nitoriti iwọ ti kọ̀ ọ̀rọ Oluwa, Oluwa si ti kọ̀ iwọ lati ma jẹ ọba lori Israeli.

27. Bi Samueli si ti yipada lati lọ, o si di ẹ̀wu ileke rẹ̀ mu, o si faya mọ̃ lọwọ́.

28. Samueli si wi fun u pe, Oluwa fa ijọba Israeli ya kuro lọwọ rẹ loni, o si fi fun aladugbo rẹ kan, ti o sàn ju ọ lọ.

29. Agbara Israeli kì yio ṣeke bẹ̃ni kì yio si ronupiwada: nitoripe ki iṣe ẹda ti yio fi ronupiwada.

30. O si wipe, emi ti dẹ̀ṣẹ: ṣugbọn bu ọlá fun mi, jọwọ, niwaju awọn agbãgbà enia mi, ati niwaju Israeli, ki o si tun yipada pẹlu mi, ki emi ki o le tẹriba niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ.

31. Samueli si yipada, o si tẹle Saulu; Saulu si tẹriba niwaju Oluwa.

32. Samueli si wipe, Mu Agagi ọba awọn ara Amaleki na tọ̀ mi wá nihinyi. Agagi si tọ̀ ọ wá ni idaraya. Agagi si wipe, Nitotọ ikoro ikú ti kọja.

33. Samueli si wipe, Gẹgẹ bi idà rẹ ti sọ awọn obinrin di alaili ọmọ, bẹ̃ gẹgẹ ni iya rẹ yio si di alaili ọmọ larin obinrin. Samueli si pa Agagi niwaju Oluwa ni Gilgali.

34. Samueli si lọ si Rama; Saulu si goke lọ si ile rẹ̀ ni Gibea ti Saulu.

35. Samueli kò si tun pada wá mọ lati wo Saulu titi o fi di ọjọ ikú rẹ̀: ṣugbọn Samueli kãnu fun Saulu: o si dùn Oluwa nitori on fi Saulu jẹ ọba lori Israeli.

Ka pipe ipin 1. Sam 15