Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 15:16-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Samueli si wi fun Saulu pe, Duro, emi o si sọ eyi ti Oluwa wi fun mi li alẹ yi. On si wi fun u pe, Ma wi.

17. Samueli si wipe, Iwọ kò ha kere loju ara rẹ nigbati a fi ọ ṣe olori ẹya Israeli, ti Oluwa fi àmi ororo sọ ọ di ọba Israeli?

18. Oluwa si rán ọ ni iṣẹ, o si wipe, Lọ, ki o si pa awọn ẹlẹṣẹ ara Amaleki run, ki o si ba wọn jà titi o fi run wọn.

19. Eha si ti ṣe ti iwọ kò fi gbọ́ ohùn Oluwa ṣugbọn iwọ si sare si ikogun, ti iwọ si ṣe buburu li oju Oluwa.

20. Saulu si wi fun Samueli pe, Nitotọ, emi gbà ohùn Oluwa gbọ́, emi si ti lọ li ọ̀na ti Oluwa ran mi, emi si ti mu Agagi ọba Amaleki wá, emi si ti pa ara Amaleki run.

21. Ṣugbọn awọn enia na ti mu ninu ikogun, agutan ati malu, pàtaki nkan wọnni ti a ba pa run, lati fi rubọ si Oluwa Ọlọrun rẹ ni Gilgali.

22. Samueli si wipe, Oluwa ha ni inu-didun si ọrẹ sisun ati ẹbọ bi pe ki a gbà ohùn Oluwa gbọ́? kiye si i, igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilẹ̀ si sàn jù ọra àgbo lọ.

23. Nitoripe iṣọtẹ dabi ẹ̀ṣẹ afọṣẹ, ati agidi gẹgẹ bi ìwa buburu ati ibọriṣa. Nitoripe iwọ kọ̀ ọ̀rọ Oluwa, on si kọ̀ ọ li ọba.

Ka pipe ipin 1. Sam 15