Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 15:12-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nigbati Samueli si dide ni kutukutu owurọ̀ lati pade Saulu, nwọn si sọ fun Samueli pe, Saulu ti wá si Karmeli, sa wõ, on kọ ibi kan fun ara rẹ̀ o si ti lọ, o si kọja siwaju, o si sọkalẹ lọ si Gilgali.

13. Samueli si tọ Saulu wá: Saulu si wi fun u pe, Alabukún ni ọ lati ọdọ Oluwa wá: emi ti ṣe eyi ti Oluwa ran mi.

14. Samueli si wipe, njẹ ewo ni igbe agutan ti emi ngbọ́ li eti mi, ati igbe malu ti emi ngbọ́?

15. Saulu si wi fun u pe, eyi ti nwọn mu ti Amaleki wá ni, ti awọn enia dasi ninu awọn agutan ton ti malu ti o dara julọ lati fi rubọ si Oluwa Ọlọrun rẹ; a si pa eyi ti o kù run.

16. Samueli si wi fun Saulu pe, Duro, emi o si sọ eyi ti Oluwa wi fun mi li alẹ yi. On si wi fun u pe, Ma wi.

17. Samueli si wipe, Iwọ kò ha kere loju ara rẹ nigbati a fi ọ ṣe olori ẹya Israeli, ti Oluwa fi àmi ororo sọ ọ di ọba Israeli?

18. Oluwa si rán ọ ni iṣẹ, o si wipe, Lọ, ki o si pa awọn ẹlẹṣẹ ara Amaleki run, ki o si ba wọn jà titi o fi run wọn.

19. Eha si ti ṣe ti iwọ kò fi gbọ́ ohùn Oluwa ṣugbọn iwọ si sare si ikogun, ti iwọ si ṣe buburu li oju Oluwa.

Ka pipe ipin 1. Sam 15