Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 11:7-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si mu malu meji, o rẹ́ wọn wẹwẹ, o si ran wọn si gbogbo agbegbe Israeli nipa ọwọ́ awọn onṣẹ na, wipe, Ẹnikẹni ti o wu ki o ṣe ti ko ba tọ Saulu ati Samueli lẹhin, bẹ̃ gẹgẹ li a o ṣe si malu rẹ̀. Ibẹ̀ru Oluwa si mu awọn enia na, nwọn si jade bi enia kanṣoṣo.

8. O si kà wọn ni Beseki, awọn ọmọ Israeli si jẹ ọkẹ mẹ̃dogun enia; awọn ọkunrin Juda si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun.

9. Nwọn si wi fun awọn iranṣẹ na ti o ti wá pe, Bayi ni ki ẹ wi fun awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi; Li ọla, lakoko igbati õrùn ba mu, ẹnyin o ni iranlọwọ. Awọn onṣẹ na wá, nwọn rò o fun awọn ọkunrin Jabeṣi; nwọn si yọ̀.

10. Nitorina awọn ọkunrin Jabeṣi wi pe, lọla awa o jade tọ nyin wá, ẹnyin o si fi wa, ṣe bi gbogbo eyi ti o tọ loju nyin.

11. O si ri bẹ̃ lọla na, Saulu si ya awọn enia na si ẹgbẹ mẹta; nwọn si wá ãrin ogun na ni iṣọ owurọ̀, nwọn si pa awọn ara Ammoni titi o fi di igba imoru ọjọ: o si ṣe awọn iyoku fọnka, tobẹ̃ ti meji wọn ko kù ni ibi kan.

Ka pipe ipin 1. Sam 11