Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 11:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Awọn iranṣẹ na si wá si Gibea ti Saulu, nwọn rohìn na li eti awọn enia: gbogbo enia na si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun.

5. Si kiye si i, Saulu bọ̀ wá ile lẹhin ọwọ́ malu lati papa wá; Saulu si wipe, Ẽṣe awọn enia ti nwọn fi nsọkun? Nwọn si sọ ọ̀rọ awọn ọkunrin Jabeṣi fun u.

6. Ẹmi Ọlọrun si bà le Saulu nigbati o gbọ́ ọ̀rọ wọnni, inu rẹ̀ si ru pipọ.

7. O si mu malu meji, o rẹ́ wọn wẹwẹ, o si ran wọn si gbogbo agbegbe Israeli nipa ọwọ́ awọn onṣẹ na, wipe, Ẹnikẹni ti o wu ki o ṣe ti ko ba tọ Saulu ati Samueli lẹhin, bẹ̃ gẹgẹ li a o ṣe si malu rẹ̀. Ibẹ̀ru Oluwa si mu awọn enia na, nwọn si jade bi enia kanṣoṣo.

8. O si kà wọn ni Beseki, awọn ọmọ Israeli si jẹ ọkẹ mẹ̃dogun enia; awọn ọkunrin Juda si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun.

9. Nwọn si wi fun awọn iranṣẹ na ti o ti wá pe, Bayi ni ki ẹ wi fun awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi; Li ọla, lakoko igbati õrùn ba mu, ẹnyin o ni iranlọwọ. Awọn onṣẹ na wá, nwọn rò o fun awọn ọkunrin Jabeṣi; nwọn si yọ̀.

10. Nitorina awọn ọkunrin Jabeṣi wi pe, lọla awa o jade tọ nyin wá, ẹnyin o si fi wa, ṣe bi gbogbo eyi ti o tọ loju nyin.

11. O si ri bẹ̃ lọla na, Saulu si ya awọn enia na si ẹgbẹ mẹta; nwọn si wá ãrin ogun na ni iṣọ owurọ̀, nwọn si pa awọn ara Ammoni titi o fi di igba imoru ọjọ: o si ṣe awọn iyoku fọnka, tobẹ̃ ti meji wọn ko kù ni ibi kan.

12. Awọn enia na si wi fun Samueli, pe, Tani wipe, Saulu yio ha jọba lori wa? mu awọn ọkunrin na wá, a o si pa wọn.

Ka pipe ipin 1. Sam 11