Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 11:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NAHAṢI ara Ammoni si goke wá, o si do ti Jabeṣi-Gileadi: gbogbo ọkunrin Jabeṣi si wi fun Nahaṣi, pe, Ba wa da majẹmu, awa o si ma sìn ọ.

2. Nahaṣi ara Ammoni na si da wọn lohùn pe, Nipa bayi li emi o fi ba nyin da majẹmu, nipa yiyọ gbogbo oju ọtun nyin kuro, emi o si fi i ṣe ẹlẹyà li oju gbogbo Israeli.

3. Awọn agba Jabeṣi si wi fun u pe, Fun wa li ayè ni ijọ meje, awa o si ran onṣẹ si gbogbo agbegbe Israeli bi ko ba si ẹniti yio gbà wa, awa o si jade tọ ọ wá.

4. Awọn iranṣẹ na si wá si Gibea ti Saulu, nwọn rohìn na li eti awọn enia: gbogbo enia na si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun.

5. Si kiye si i, Saulu bọ̀ wá ile lẹhin ọwọ́ malu lati papa wá; Saulu si wipe, Ẽṣe awọn enia ti nwọn fi nsọkun? Nwọn si sọ ọ̀rọ awọn ọkunrin Jabeṣi fun u.

6. Ẹmi Ọlọrun si bà le Saulu nigbati o gbọ́ ọ̀rọ wọnni, inu rẹ̀ si ru pipọ.

7. O si mu malu meji, o rẹ́ wọn wẹwẹ, o si ran wọn si gbogbo agbegbe Israeli nipa ọwọ́ awọn onṣẹ na, wipe, Ẹnikẹni ti o wu ki o ṣe ti ko ba tọ Saulu ati Samueli lẹhin, bẹ̃ gẹgẹ li a o ṣe si malu rẹ̀. Ibẹ̀ru Oluwa si mu awọn enia na, nwọn si jade bi enia kanṣoṣo.

8. O si kà wọn ni Beseki, awọn ọmọ Israeli si jẹ ọkẹ mẹ̃dogun enia; awọn ọkunrin Juda si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun.

9. Nwọn si wi fun awọn iranṣẹ na ti o ti wá pe, Bayi ni ki ẹ wi fun awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi; Li ọla, lakoko igbati õrùn ba mu, ẹnyin o ni iranlọwọ. Awọn onṣẹ na wá, nwọn rò o fun awọn ọkunrin Jabeṣi; nwọn si yọ̀.

10. Nitorina awọn ọkunrin Jabeṣi wi pe, lọla awa o jade tọ nyin wá, ẹnyin o si fi wa, ṣe bi gbogbo eyi ti o tọ loju nyin.

Ka pipe ipin 1. Sam 11