Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 10:19-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ẹnyin si kọ̀ Ọlọrun nyin loni, ẹniti on tikara rẹ́ ti gbà nyin kuro lọwọ́ gbogbo awọn ọta nyin, ati gbogbo wahala nyin; ẹnyin si ti wi fun u pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn awa nfẹ ki o fi ẹnikan jọba lori wa. Nisisiyi ẹ duro niwaju Oluwa nipa ẹyà nyin, ati nipa ẹgbẹgbẹrun nyin.

20. Samueli si mu ki gbogbo ẹya Israeli sunmọ tosi, a si mu ẹya Benjamini.

21. On si mu ki ẹya Benjamini sunmọ tosi nipa idile wọn, a mu idile Matri, a si mu Saulu ọmọ Kiṣi: nigbati nwọn si wá a kiri, nwọn kò si ri i.

22. Nitorina nwọn si tun bere lọdọ Oluwa sibẹ bi ọkunrin na yio wá ibẹ̀. Oluwa si dahùn wipe, Wõ, o pa ara rẹ̀ mọ lãrin ohun-elò.

23. Nwọn sare, nwọn si mu u lati ibẹ̀ wá: nigbati o si duro lãrin awọn enia na, o si ga jù gbogbo wọn lọ lati ejika rẹ̀ soke.

24. Samueli si wi fun gbogbo awọn enia na pe, Ẹnyin kò ri ẹniti Oluwa yàn fun ara rẹ̀, pe, ko si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo enia na? Gbogbo enia si ho ye, nwọn si wipe, Ki Ọba ki o pẹ!

25. Samueli si sọ ìwa ijọba fun awọn enia na. O si kọ ọ sinu iwe, o si fi i siwaju Oluwa. Samueli si rán gbogbo enia na lọ, olukuluku si ile rẹ̀.

26. Saulu pẹlu si lọ si ile rẹ̀ si Gibea; ẹgbẹ awọn alagbara ọkunrin si ba a lọ, ọkàn awọn ẹniti Ọlọrun tọ́.

27. Ṣugbọn awọn ọmọ Beliali wipe, Ọkunrin yi yio ti ṣe gbà wa? Nwọn kẹgàn rẹ̀, nwọn ko si mu ọrẹ wá fun u. On si dakẹ.

Ka pipe ipin 1. Sam 10