Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 1:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ọkunrin kan wà, ara Ramataim-sofimu, li oke Efraimu, orukọ rẹ̀ ama jẹ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ara Efrata.

2. O si ni aya meji; orukọ ekini ama jẹ Hanna, orukọ ekeji a si ma jẹ Peninna: Peninna si bimọ, ṣugbọn Hanna kò bi.

3. Ọkunrin yi a ma ti ilu rẹ̀ lọ lọdọdun lati sìn ati lati ṣe irubọ si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Ṣilo. Ọmọ Eli mejeji Hofni ati Finehasi alufa Oluwa, si wà nibẹ.

4. Nigbati o si di akoko ti Elkana ṣe irubọ, o fi ipin fun Peninna aya rẹ̀, ati fun gbogbo ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.

5. Ṣugbọn Hanna li on fi ipin ẹni meji fun; nitori ti o fẹ Hanna: ṣugbọn Oluwa ti se e ni inu.

6. Orogún rẹ̀ pẹlu a si ma tọ́ ọ gidigidi lati mu u binu, nitoriti Oluwa ti se e ni inu.

7. Bi on iti ma ṣe bẹ̃ lọdọdun, nigbati Hanna ba goke lọ si ile Oluwa, bẹni Peninna ima bà a ni inu jẹ; nitorina ama sọkun, kò si jẹun.

8. Nigbana ni Elkana ọkọ rẹ̀ si sọ fun u pe, Hanna, ẽṣe ti iwọ nsọkun? ẽṣe ti iwọ kò si jẹun? ẽsi ti ṣe ti inu rẹ fi bajẹ? emi ko ha sàn fun ọ ju ọmọ mẹwa lọ bi?

9. Bẹ̃ni Hanna si dide lẹhin igbati wọn jẹ, ti nwọn si mu tan ni Ṣilo. Eli alufa si joko lori apoti li ẹba opó tempili Oluwa.

10. On si wà ninu ibinujẹ ọkàn, o si mbẹ Oluwa, o si sọkun gidigidi.

11. On si jẹ́'jẹ, o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, bi iwọ nitõtọ ba bojuwo ipọnju iranṣẹbinrin rẹ, ti o si ranti mi, ti iwọ kò si gbagbe iranṣẹbinrin rẹ, ṣugbọn bi iwọ ba fi ọmọkunrin kan fun iranṣẹbinrin rẹ, nigbana li emi o fi i fun Oluwa ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, abẹ kì yio si kàn a lori.

Ka pipe ipin 1. Sam 1