Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 7:5-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ati awọn arakunrin wọn ninu gbogbo idile Issakari jẹ akọni alagbara enia, ni kikaye gbogbo wọn nipa iran wọn, nwọn jẹ ẹgbamẹtalelogoji o le ẹgbẹrun.

6. Awọn ọmọ Benjamini: Bela, ati Bekeri, ati Jediaeli, mẹta.

7. Awọn ọmọ Bela; Esboni, ati Ussi, ati Ussieli ati Jerimoti ati Iri, marun; awọn olori ile baba wọn, akọni alagbara enia; a si kaye wọn nipa iran wọn si ẹgbãmọkanla enia o le mẹrinlelọgbọ̀n.

8. Awọn ọmọ Bekeri: Semira, ati Joaṣi, ati Elieseri, ati Elioeni, ati Omri, ati Jeremotu, ati Abiah, ati Anatoti, ati Alameti. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Bekeri.

9. Ati iye wọn, ni idile wọn nipa iran wọn, awọn olori ile baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbawa o le igba.

10. Awọn ọmọ Jediaeli; Bilhani: ati awọn ọmọ Bilhani: Jeuṣi, ati Benjamini, ati Ehudi, ati Kenaana, ati Setani, ati Tarṣiṣi ati Ahisahari.

11. Gbogbo awọn wọnyi ọmọ Jediaeli, nipa olori awọn baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbãjọ o le ẹgbẹfa ọmọ-ogun, ti o le jade lọ si ogun.

12. Ati Ṣuppimu, ati Huppimu, awọn ọmọ Iri, ati Huṣimu, awọn ọmọ Aheri.

Ka pipe ipin 1. Kro 7