37. Beseri, ati Hodi, ati Ṣamma, ati Ṣilṣa, ati Itrani, ati Beera.
38. Ati awọn ọmọ Jeteri: Jefunne, ati Pispa, ati Ara.
39. Ati awọn ọmọ Ulla: Ara, ati Hanieli, ati Resia.
40. Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Aṣeri, awọn olori ile baba wọn, aṣayan alagbara akọni enia, olori ninu awọn ijoye. Iye awọn ti a kà yẹ fun ogun, ati fun ijà ni idile wọn jẹ, ẹgbã mẹtala ọkunrin.