Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 7:17-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Awọn ọmọ Ulamu: Bedani. Awọn wọnyi li awọn ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse.

18. Arabinrin rẹ̀, Hammoleketi, bi Iṣodi, ati Abieseri, ati Mahala.

19. Ati awọn ọmọ Ṣemida ni, Ahiani, ati Ṣekemu, ati Likki, ati Aniamu.

20. Awọn ọmọ Efraimu: Ṣutela, ati Beredi ọmọ rẹ̀, ati Tahati, ọmọ rẹ̀, ati Elada, ọmọ rẹ̀, ati Tahati ọmọ rẹ̀.

21. Ati Sabadi ọmọ rẹ̀, ati Ṣutela ọmọ rẹ̀, ati Eseri, ati Eleadi, ẹniti awọn ọkunrin Gati, ti a bi ni ilẹ na, pa, nitori nwọn sọkalẹ wá lati kó ẹran ọ̀sin wọn lọ.

22. Efraimu baba wọn si ṣọ̀fọ li ọjọ pupọ, awọn arakunrin rẹ̀ si wá lati tù u ninu.

23. Nigbati o si wọle tọ̀ aya rẹ̀ lọ, o loyun o si bi ọmọ kan, on si pè orukọ rẹ̀ ni Beria, nitoriti ibi ba ile rẹ̀.

24. Ọmọ rẹ̀ obinrin ni Sera, ẹniti o tẹ̀ Bet-horoni dó, ti isalẹ ati ti òke, ati Usseni Ṣera.

25. Refa si ni ọmọ rẹ̀ ọkunrin, Reṣefu pẹlu, ati Tela ọmọ rẹ̀, ati Tahani ọmọ rẹ̀.

26. Laadani ọmọ rẹ̀, Ammihudi ọmọ rẹ̀, Eliṣama ọmọ rẹ̀.

27. Nuni ọmọ rẹ̀, Joṣua ọmọ rẹ̀,

Ka pipe ipin 1. Kro 7