Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 7:10-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Awọn ọmọ Jediaeli; Bilhani: ati awọn ọmọ Bilhani: Jeuṣi, ati Benjamini, ati Ehudi, ati Kenaana, ati Setani, ati Tarṣiṣi ati Ahisahari.

11. Gbogbo awọn wọnyi ọmọ Jediaeli, nipa olori awọn baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbãjọ o le ẹgbẹfa ọmọ-ogun, ti o le jade lọ si ogun.

12. Ati Ṣuppimu, ati Huppimu, awọn ọmọ Iri, ati Huṣimu, awọn ọmọ Aheri.

13. Awọn ọmọ Naftali: Jasieli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣallumu, awọn ọmọ Bilha.

14. Awọn ọmọ Manasse; Aṣrieli, ti aya rẹ̀ bi: (ṣugbọn obinrin rẹ̀, ara Aramu, bi Makiri baba Gileadi:

15. Makiri si mu arabinrin Huppimu, ati Ṣuppimu li aya, orukọ arabinrin ẹniti ijẹ Maaka,) ati orukọ ekeji ni Selofehadi: Selofehadi si ni awọn ọmọbinrin.

16. Maaka, obinrin Makiri, bi ọmọ, on si pè orukọ rẹ̀ ni Pereṣi: orukọ arakunrin rẹ̀ ni Ṣereṣi; ati awọn ọmọ rẹ̀ ni Ulamu ati Rakemu.

Ka pipe ipin 1. Kro 7