Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 7:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN ọmọ Issakari si ni, Tola, ati Pua, Jaṣubu, ati Ṣimroni, mẹrin.

2. Ati awọn ọmọ Tola; Ussi, ati Refaiah, ati Jerieli, ati Jamai, ati Jibsamu ati Samueli, awọn olori ile baba wọn, eyini ni ti Tola: akọni alagbara enia ni wọn ni iran wọn; iye awọn ẹniti o jẹ ẹgbã mọkanla o le ẹgbẹta li ọjọ Dafidi.

3. Awọn ọmọ Ussi: Israhiah ati awọn ọmọ Israhiah; Mikaeli, ati Obadiah, ati Joeli, ati Iṣiah, marun: gbogbo wọn li olori.

4. Ati pẹlu wọn, nipa iran wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, ni awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun fun ogun, ẹgbã mejidilogun enia: nitoriti nwọn ni ọ̀pọlọpọ obinrin ati ọmọ ọkunrin.

5. Ati awọn arakunrin wọn ninu gbogbo idile Issakari jẹ akọni alagbara enia, ni kikaye gbogbo wọn nipa iran wọn, nwọn jẹ ẹgbamẹtalelogoji o le ẹgbẹrun.

Ka pipe ipin 1. Kro 7