Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 6:64-80 Yorùbá Bibeli (YCE)

64. Awọn ọmọ Israeli fi ilu wọnyi fun awọn ọmọ Lefi pẹlu ìgberiko wọn.

65. Nwọn si fi keké fi ilu wọnyi ti a da orukọ wọn fun ni lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini.

66. Ati iyokù ninu idile awọn ọmọ Kohati ni ilu li àgbegbe wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu.

67. Nwọn si fi ninu ilu àbo fun wọn, Ṣekemu li òke Efraimu pẹlu ìgberiko rẹ̀; Geseri pẹlu ìgberiko rẹ̀,

68. Ati Jokneamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-horoni pẹlu ìgberiko rẹ̀,

69. Ati Aijaloni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Gatrimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀:

70. Ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse; Aneri pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bileamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, fun idile awọn ọmọ Kohati iyokù.

71. Awọn ọmọ Gerṣomu lati inu idile àbọ ẹ̀ya Manasse li a fi Golani ni Baṣani fun pẹlu ìgberiko rẹ̀; ati Aṣtaroti pẹlu ìgberiko rẹ̀,

72. Ati lati inu ẹ̀ya Issakari; Kadeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀; Daberati pẹlu ìgberiko rẹ̀,

73. Ati Ramoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anemu pẹlu ìgberiko rẹ̀:

74. Ati lati inu ẹ̀ya Aṣeri; Maṣali pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Abdoni pẹlu ìgberiko rẹ̀.

75. Ati Hakoku pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Rehobu pẹlu ìgberiko rẹ̀:

76. Ati lati inu ẹ̀ya Naftali; Kedeṣi ni Galili pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Hammoni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Kirjataimu pẹlu ìgberiko rẹ̀.

77. Fun iyokù awọn ọmọ Merari li a fi Rimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun, Tabori pẹlu ìgberiko rẹ̀, lati inu ẹ̀ya Sebuluni:

78. Ati li apa keji Jordani leti Jeriko, ni iha ariwa Jordani, li a fi Beseri li aginju pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jasa pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun wọn, lati inu ẹ̀ya Rubeni,

79. Ati Kedemoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mefaati pẹlu ìgberiko rẹ̀:

80. Ati lati inu ẹ̀ya Gadi, Ramoti ni Gileadi pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mahanaimu pẹlu ìgberiko rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Kro 6