Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 6:59-70 Yorùbá Bibeli (YCE)

59. Ati Aṣani pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-ṣemeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀:

60. Ati lati inu ẹ̀ya Benjamini; Geba pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Alemeti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anatoti pẹlu ìgberiko rẹ̀. Gbogbo ilu wọn ni idile wọn jẹ ilu mẹtala.

61. Ati fun awọn ọmọ Kohati, ti o kù ni idile ẹ̀ya na, li a fi keke fi ilu mẹwa fun, ninu àbọ ẹ̀ya, ani lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse.

62. Ati fun awọn ọmọ Gerṣomu ni idile wọn, lati inu ẹ̀ya Issakari, ati inu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati lati inu ẹ̀ya Manasse ni Baṣani, ilu mẹtala.

63. Fun awọn ọmọ Merari ni idile wọn li a fi keké fi ilu mejila fun, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati lati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni,

64. Awọn ọmọ Israeli fi ilu wọnyi fun awọn ọmọ Lefi pẹlu ìgberiko wọn.

65. Nwọn si fi keké fi ilu wọnyi ti a da orukọ wọn fun ni lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini.

66. Ati iyokù ninu idile awọn ọmọ Kohati ni ilu li àgbegbe wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu.

67. Nwọn si fi ninu ilu àbo fun wọn, Ṣekemu li òke Efraimu pẹlu ìgberiko rẹ̀; Geseri pẹlu ìgberiko rẹ̀,

68. Ati Jokneamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-horoni pẹlu ìgberiko rẹ̀,

69. Ati Aijaloni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Gatrimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀:

70. Ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse; Aneri pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bileamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, fun idile awọn ọmọ Kohati iyokù.

Ka pipe ipin 1. Kro 6