Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 6:49-64 Yorùbá Bibeli (YCE)

49. Ṣugbọn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ nrubọ lori pẹpẹ ẹbọ sisun, ati lori pẹpẹ turari, a si yàn wọn si gbogbo iṣẹ ibi mimọ́-jùlọ, ati lati ṣe ètutu fun Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ti pa li aṣẹ.

50. Wọnyi si li awọn ọmọ Aaroni; Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀,

51. Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀,

52. Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀,

53. Sadoku ọmọ rẹ̀, Ahimaasi ọmọ rẹ̀.

54. Wọnyi si ni ibùgbe wọn gẹgẹ bi budo wọn li àgbegbe wọn, ti awọn ọmọ Aaroni, ti idile awọn ọmọ Kohati: nitori ti wọn ni ipin ikini.

55. Nwọn si fun wọn ni Hebroni ni ilẹ Juda, ati ìgberiko rẹ̀ yi i kakiri.

56. Ṣugbọn oko ilu na, ati ileto wọn, ni nwọn fun Kalebu ọmọ Jefunne.

57. Nwọn si fi ilu Juda fun awọn ọmọ Aaroni, ani Hebroni, ilu àbo ati Libna pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jattiri, ati Eṣtemoa, pẹlu ìgberiko wọn,

58. Ati Hileni pẹlu ìgberiko rẹ̀, Debiri pẹlu ìgberiko rẹ̀,

59. Ati Aṣani pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-ṣemeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀:

60. Ati lati inu ẹ̀ya Benjamini; Geba pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Alemeti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anatoti pẹlu ìgberiko rẹ̀. Gbogbo ilu wọn ni idile wọn jẹ ilu mẹtala.

61. Ati fun awọn ọmọ Kohati, ti o kù ni idile ẹ̀ya na, li a fi keke fi ilu mẹwa fun, ninu àbọ ẹ̀ya, ani lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse.

62. Ati fun awọn ọmọ Gerṣomu ni idile wọn, lati inu ẹ̀ya Issakari, ati inu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati lati inu ẹ̀ya Manasse ni Baṣani, ilu mẹtala.

63. Fun awọn ọmọ Merari ni idile wọn li a fi keké fi ilu mejila fun, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati lati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni,

64. Awọn ọmọ Israeli fi ilu wọnyi fun awọn ọmọ Lefi pẹlu ìgberiko wọn.

Ka pipe ipin 1. Kro 6